18 Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọ́n fi Ṣerebaya, ọlọ́gbọ́n eniyan kan ranṣẹ sí wa. Ọmọ Israẹli ni, láti inú àwọn ọmọ Mahili, ninu ẹ̀yà Lefi: wọ́n fi ranṣẹ pẹlu àwọn ọmọ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogun.
19 Wọ́n tún rán Haṣabaya, òun ati Jeṣaya ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Merari; pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ wọn. Gbogbo wọn jẹ́ ogún,
20 láì tíì ka igba ó lé ogún (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tí Dafidi ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a kọ orúkọ wọn sinu ìwé.
21 Lẹ́yìn náà, mo pàṣẹ létí odò Ahafa pé kí á gbààwẹ̀, kí á lè rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọrun wa, kí á sì bèèrè ìtọ́sọ́nà fún ara wa ati àwọn ọmọ wa, ati gbogbo ohun ìní wa.
22 Ìtìjú ni ó jẹ́ fún mi láti bèèrè fún ọ̀wọ́ ọmọ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tí yóo dáàbò bò wá ninu ìrìn àjò wa, nítorí mo ti sọ fún ọba pé Ọlọrun wa a máa ṣe rere fún àwọn tí wọ́n bá ń gbọ́ tirẹ̀; Ṣugbọn a máa fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn kò bá tẹ̀lé e.
23 Nítorí náà, a gba ààwẹ̀, a sì gbadura sí Ọlọ́run, ó sì gbọ́ tiwa.
24 Lẹ́yìn náà mo ya àwọn àgbààgbà alufaa mejila sọ́tọ̀: Ṣerebaya, Haṣabaya ati mẹ́wàá ninu àwọn arakunrin wọn.