Ẹsira 9:1-6 BM

1 Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n ní: “Àwọn ọmọ Israẹli pẹlu àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò ninu ìwà ìríra àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi ati àwọn ará Jebusi, ti àwọn ará Amoni ati àwọn ará Moabu, àwọn ará Ijipti, ati àwọn ará Amori.

2 Wọ́n ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn fún ara wọn ati fún àwọn ọmọ wọn; àwọn ẹ̀yà mímọ́ sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà jù ni àwọn olórí ati àwọn eniyan pataki ní Israẹli.”

3 Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fa aṣọ ati agbádá mi ya, láti fi ìbànújẹ́ mi hàn, mo sì fa irun orí ati irùngbọ̀n mi tu; mo sì jókòó pẹlu ìbànújẹ́.

4 Mo jókòó bẹ́ẹ̀ títí di àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. Gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ̀gbà yí mi ká nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé.

5 Ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́, mo dìde kúrò níbi tí mo ti ń gbààwẹ̀ pẹlu aṣọ ati agbádá mi tí ó ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́wọ́ sí OLUWA Ọlọrun mi, mo gbadura pé:

6 “Ọlọrun mi, ojú tì mí tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè gbójú sókè níwájú rẹ. Ìwà burúkú wa pọ̀ pupọ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní ìpele ìpele, sì ga títí kan ọ̀run.