11 àní, òfin tí o ṣe, tí o fi rán àwọn wolii sí wa pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìríra, pẹlu ìwà ẹ̀gbin àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ náà ti sọ ọ́ di aláìmọ́.
12 Nítorí náà, ẹ má fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọkunrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọkunrin yín. Ẹ kò gbọdọ̀ wá ire wọn tabi alaafia, kí ẹ lè lágbára, kí ẹ lè jẹ èrè ilẹ̀ náà, kí ó sì lè jẹ́ ohun ìní fún àwọn ìran yín títí lae.
13 Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa, nítorí ìwà burúkú wa ati ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí a dá, a rí i pé ìyà tí ìwọ Ọlọrun fi jẹ wá kéré sí ẹ̀ṣẹ̀ wa; o jẹ́ kí àwa tí a pọ̀ tó báyìí ṣẹ́kù sílẹ̀.
14 Ǹjẹ́ àwa tí a ṣẹ́kù yìí tún gbọdọ̀ máa rú òfin rẹ, kí á máa fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń ṣe ohun ìríra? Ǹjẹ́ o kò ní bínú sí wa tóbẹ́ẹ̀ tí o óo fi pa wá run, tí a kò fi ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan mọ́ tabi kí ẹyọ ẹnìkan sá àsálà?
15 OLUWA Ọlọrun Israẹli, olódodo ni ọ́, nítorí díẹ̀ ninu wa ṣẹ́kù tí a sá àsálà títí di òní yìí. A wà níwájú rẹ báyìí pẹlu ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè dúró níwájú rẹ báyìí.”