Ẹsira 9:4-10 BM

4 Mo jókòó bẹ́ẹ̀ títí di àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. Gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ̀gbà yí mi ká nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé.

5 Ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́, mo dìde kúrò níbi tí mo ti ń gbààwẹ̀ pẹlu aṣọ ati agbádá mi tí ó ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́wọ́ sí OLUWA Ọlọrun mi, mo gbadura pé:

6 “Ọlọrun mi, ojú tì mí tóbẹ́ẹ̀ tí n kò lè gbójú sókè níwájú rẹ. Ìwà burúkú wa pọ̀ pupọ níwájú rẹ, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní ìpele ìpele, sì ga títí kan ọ̀run.

7 Láti ayé àwọn baba wa títí di ìsinsìnyìí, ni àwa eniyan rẹ ti ń dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwọn ọba ati àwọn alufaa wa ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọba ilẹ̀ àjèjì; wọ́n pa wá, wọ́n dè wá ní ìgbèkùn, wọ́n sì kó wa lẹ́rù. A wá di ẹni ẹ̀gàn títí di òní.

8 Ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ní àkókò yìí, OLUWA Ọlọrun wa, o ṣàánú wa, o dá díẹ̀ sí ninu wa, à ń gbé ní àìléwu ní ibi mímọ́ rẹ. O jẹ́ kí ara dẹ̀ wá díẹ̀ ní oko ẹrú, o sì ń mú inú wa dùn.

9 Ẹrú ni wá; sibẹ ìwọ Ọlọrun wa kò fi wá sílẹ̀ ninu oko ẹrú, ṣugbọn o fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa, lọ́dọ̀ àwọn ọba Pasia; o sọ wá jí láti kọ́ ilé Ọlọrun wa, láti tún àwọn àlàpà rẹ̀ mọ ati láti mọ odi yí Judia ati Jerusalẹmu ká.

10 “Áà, Ọlọrun wa, kí ni a tún lè wí lẹ́yìn èyí? Nítorí a ti kọ òfin rẹ sílẹ̀,