1 Tẹ́lẹ̀ rí, bí ẹ̀yà Efuraimu bá sọ̀rọ̀, àwọn eniyan a máa wárìrì; wọ́n níyì láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, ṣugbọn nítorí pé wọ́n bọ oriṣa Baali, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú.
2 Nisinsinyii, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yá ère fún ara wọn; ère fadaka, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, Wọ́n ń sọ pé, “Ẹ wá rúbọ sí i.” Eniyan wá ń fi ẹnu ko ère mààlúù lẹ́nu!
3 Nítorí náà, wọn óo dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí máa ń yára gbẹ, wọ́n óo dàbí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kúrò ní ibi ìpakà, ati bí èéfín tí ń jáde láti ojú fèrèsé.
4 OLUWA ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, láti ìgbà tí ẹ ti wà ní ilẹ̀ Ijipti: ẹ kò ní Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ní olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi.
5 Èmi ni mo ṣe ìtọ́jú yín nígbà tí ẹ wà ninu aṣálẹ̀, ninu ilẹ̀ gbígbẹ;
6 ṣugbọn nígbà tí ẹ jẹun yó tán, ẹ̀ ń gbéraga, ẹ gbàgbé mi.
7 Nítorí náà, bíi kinniun ni n óo ṣe si yín, n óo lúgọ lẹ́bàá ọ̀nà bí àmọ̀tẹ́kùn;
8 n óo yọ si yín bí ẹranko beari tí wọ́n kó lọ́mọ lọ, n óo sì fa àyà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. N óo ya yín jẹ bíi kinniun, bí ẹranko burúkú ṣe ń fa ẹran ya.
9 “N óo pa yín run, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; ta ni yóo ràn yín lọ́wọ́?
10 Níbo ni ọba yín wà nisinsinyii, tí yóo gbà yín là? Níbo ni àwọn olórí yín wà, tí wọn yóo gbèjà yín? Àwọn tí ẹ bèèrè fún, tí ẹ ní, ‘Ẹ fún wa ní ọba ati àwọn ìjòyè.’
11 Pẹlu ibinu, ni mo fi fun yín ní àwọn ọba yín, ìrúnú ni mo sì fi mú wọn kúrò.
12 “A ti di ẹ̀ṣẹ̀ Efuraimu ní ìtí ìtí, a ti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pamọ́.
13 Àwọn ọmọ Israẹli ní anfaani láti wà láàyè, ṣugbọn ìwà òmùgọ̀ wọn kò jẹ́ kí wọ́n lo anfaani náà. Ó dàbí ọmọ tí ó kọ̀, tí kò jáde kúrò ninu ìyá rẹ̀ ní àkókò ìrọbí.
14 N kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú, n kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ ikú. Ikú! Níbo ni àjàkálẹ̀ àrùn rẹ wà? Ìwọ isà òkú! Ìparun rẹ dà? Àánú kò sí lójú mi mọ́.
15 Bí Israẹli tilẹ̀ rúwé bí ewéko etí odò, atẹ́gùn OLUWA láti ìlà oòrùn yóo fẹ́ wá, yóo wá láti inú aṣálẹ̀; orísun rẹ̀ yóo gbẹ, ojú odò rẹ̀ yóo sì gbẹ pẹlu; a óo kó ìṣúra ati ohun èlò olówó iyebíye rẹ̀ kúrò.
16 Samaria ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi Ọlọrun rẹ̀, ogun ni yóo pa wọ́n, a óo ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, a óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”