Hosia 1 BM

1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Hosia, ọmọ Beeri nìyí, ní àkókò tí Usaya ati Jotamu, ati Ahasi, ati Hesekaya jọba ní ilẹ̀ Juda; tí Jeroboamu, ọmọ Joaṣi, sì jọba ní ilẹ̀ Israẹli.

Iyawo Hosia ati Àwọn Ọmọ Rẹ̀

2 Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.”

3 Hosia bá lọ fẹ́ iyawo kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gomeri, ọmọ Dibulaimu. Gomeri lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un.

4 OLUWA sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní Jesireeli; nítorí láìpẹ́ yìí ni n óo jẹ ìdílé Jehu níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn tí ó dá ní Jesireeli, n óo sì fi òpin sí ìjọba Israẹli.

5 Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn ọmọ ogun Israẹli ní àfonífojì Jesireeli.”

6 Gomeri tún lóyún, ó sì bí ọmọbinrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní, ‘Kò sí Àánú’; nítorí n kò ní ṣàánú àwọn eniyan Israẹli mọ́,

7 n kò sì ní dáríjì wọ́n mọ́, ṣugbọn n óo fẹ́ràn ilé Juda, n óo sì ṣàánú wọn, èmi OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n là, láìlo ọfà ati ọrun, idà tabi ogun, tabi ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin.”

8 Lẹ́yìn tí Gomeri gba ọmú lẹ́nu ‘Kò sí Àánú’ ó tún lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan.

9 OLUWA tún sọ fún Hosia pé: “Sọ ọmọ náà ní ‘Kì í ṣe Eniyan Mi’, nítorí pé ẹ̀yin ọmọ Israẹli kì í ṣe eniyan mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọrun yín.”

A óo Ra Israẹli Pada

10 Àwọn ọmọ Israẹli yóo pọ̀ sí i bí iyanrìn etí òkun tí kò ṣe é wọ̀n, tí kò sì ṣe é kà. Níbi tí a ti sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe eniyan mi”, níbẹ̀ ni a óo ti pè wọ́n ní, “ọmọ Ọlọrun Alààyè.”

11 A óo kó àwọn eniyan Israẹli ati ti Juda papọ̀, wọn óo yan olórí kanṣoṣo fún ara wọn; wọn óo sì máa ti ibẹ̀ jáde wá. Dájúdájú, ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesireeli yóo jẹ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14