1 Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
2 Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo.
3 Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.”
4 Ọlọrun ní,“N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn,n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn,nítorí n kò bínú sí wọn mọ́.
5 Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli,ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì,gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni.
6 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀;ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi,òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni.
7 Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi,wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà;wọn óo sì tanná bí àjàrà,òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni.
8 Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀,tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀.Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn.Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.”
9 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀.