Hosia 8 BM

OLUWA Bá Israẹli Wí nítorí Ìwà Ìbọ̀rìṣà

1 OLUWA ní: “Ẹ ti fèrè bọnu, nítorí ẹyẹ igún wà lórí ilé mi, nítorí pé wọ́n ti yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, wọ́n sì ti rú òfin mi.

2 Wọ́n ń ké pè mí, wọ́n ń wí pé, ‘Ọlọrun wa, àwa ọmọ Israẹli mọ̀ ọ́.’

3 Israẹli ti kọ ohun rere sílẹ̀; nítorí náà, àwọn ọ̀tá yóo máa lépa wọn.

4 “Wọ́n ń fi ọba jẹ, láìsí àṣẹ mi. Wọ́n ń yan àwọn aláṣẹ, ṣugbọn n kò mọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n ń fi fadaka ati wúrà wọn yá ère fún ìparun ara wọn.

5 Mo kọ oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù yín, ẹ̀yin ará Samaria. Inú mi ń ru sí wọn. Yóo ti pẹ́ tó kí àwọn ọmọ Israẹli tó di mímọ́?

6 Oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kì í ṣe Ọlọrun, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni, a óo sì rún ti Samaria wómúwómú.

7 Wọ́n ń gbin afẹ́fẹ́, wọn yóo sì ká ìjì líle. Ọkà tí kò bá tú, kò lè lọ́mọ, bí wọ́n bá tilẹ̀ lọ́mọ, tí wọ́n sì gbó, àwọn àjèjì ni yóo jẹ ẹ́ run.

8 A ti tú Israẹli ká, wọ́n ti kọ́ àṣàkaṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà láàrin wọn, wọ́n sì dàbí ohun èlò tí kò wúlò.

9 Nítorí pé wọ́n lọ sí Asiria, wọ́n dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń dá rìn; Efuraimu ti bẹ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wẹ̀ fún ààbò.

10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo kó wọn jọ láìpẹ́, láti jẹ wọ́n níyà, fún ìgbà díẹ̀, lọ́dọ̀ àwọn ọba alágbára tí yóo ni wọ́n lára.

11 “Nítorí Efuraimu ti tẹ́ ọpọlọpọ pẹpẹ láti dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, wọ́n ti di pẹpẹ ẹ̀ṣẹ̀ dídá fún un.

12 Bí mo tilẹ̀ kọ òfin mi sílẹ̀ ní ìgbà ẹgbẹrun, sibẹsibẹ wọn óo kà wọ́n sí nǹkan tó ṣàjèjì.

13 Wọ́n fẹ́ràn ati máa rúbọ; wọ́n ń fi ẹran rúbọ, wọ́n sì ń jẹ ẹ́; ṣugbọn inú OLUWA kò dùn sí wọn. Yóo wá ranti àìdára wọn nisinsinyii, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn; wọn óo sì pada sí Ijipti.

14 “Àwọn ọmọ Israẹli ti gbàgbé Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì ti kọ́ ààfin fún ara wọn. Àwọn ọmọ Juda ti kọ́ ọpọlọpọ ìlú olódi sí i; ṣugbọn n óo sọ iná sí àwọn ìlú wọn, yóo sì jó àwọn ibi ààbò wọn ní àjórun.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14