11 OLUWA ní, “Ọtí waini ati waini tuntun ti ra àwọn eniyan mi níyè.
12 Wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ igi gbígbẹ́, ọ̀pá wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wọn. Ẹ̀mí àgbèrè ẹ̀sìn ti mú wọn ṣáko, wọ́n ti kọ Ọlọrun wọn sílẹ̀ láti máa bọ ìbọkúbọ.
13 Wọ́n ń rúbọ lórí òkè gíga, wọ́n ń sun turari lórí òkè kéékèèké, ati lábẹ́ igi oaku, ati igi populari ati igi terebinti, nítorí òjìji abẹ́ wọn tutù. Nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin yín ṣe di aṣẹ́wó, àwọn aya yín sì di alágbèrè.
14 Ṣugbọn n kò ní jẹ àwọn ọmọbinrin yín níyà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe aṣẹ́wó, tabi kí n jẹ àwọn aya yín níyà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè; nítorí pé, àwọn ọkunrin yín pàápàá ń bá àwọn aṣẹ́wó lòpọ̀, wọ́n sì ń bá àwọn aṣẹ́wó ilé oriṣa rúbọ. Àwọn tí wọn kò bá ní ìmọ̀ yóo sì parun.
15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ìwọ Israẹli, má kó ẹ̀bi bá Juda. Má wọ Giligali lọ bọ̀rìṣà, má sì gòkè lọ sí Betafeni, má sì lọ búra níbẹ̀ pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ.’
16 Israẹli ń ṣe agídí bí ọ̀dọ́ mààlúù tí ó ya olóríkunkun; ṣe OLUWA lè máa bọ́ wọn bí aguntan nisinsinyii lórí pápá tí ó tẹ́jú.
17 Ìbọ̀rìṣà ti wọ Efuraimu lẹ́wù, ẹ fi wọ́n sílẹ̀.