4 Ṣugbọn OLUWA wí pé, “Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Efuraimu? Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Juda? Ìfẹ́ yín dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí yára á gbẹ.
5 Nítorí náà ni mo fi jẹ́ kí àwọn wolii mi ké wọn lulẹ̀, mo ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi pa wọ́n, ìdájọ́ mi sì yọ bí ìmọ́lẹ̀.
6 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú; ìmọ̀ Ọlọrun ni mo bèèrè, kì í ṣe ẹbọ sísun.
7 “Ṣugbọn wọ́n yẹ àdéhùn tí mo bá wọn ṣe, bí Adamu, wọ́n hùwà aiṣododo sí èmi Ọlọrun.
8 Gileadi ti di ìlú àwọn ẹni ibi, ó kún fún ìpànìyàn.
9 Bí àwọn ọlọ́ṣà tií ba de eniyan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alufaa kó ara wọn jọ, láti paniyan ní ọ̀nà Ṣekemu, wọ́n ń ṣe nǹkan ìtìjú láìbìkítà.
10 Mo rí ohun tí ó burú gan-an ní Israẹli; ìbọ̀rìṣà Efuraimu wà níbẹ̀, Israẹli sì ti ba ara wọn jẹ́.