Hosia 9:5-11 BM

5 Kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àsè OLUWA?

6 Wọn yóo fọ́nká lọ sí Asiria; Ijipti ni yóo gbá wọn jọ, Memfisi ni wọn yóo sin wọ́n sí, Ẹ̀gún ọ̀gàn ni yóo hù bo àwọn nǹkan èlò fadaka olówó iyebíye wọn, ẹ̀gún yóo sì hù ninu àgọ́ wọn.

7 Àkókò ìjìyà ati ẹ̀san ti dé, Israẹli yóo sì mọ̀. Ẹ̀ ń wí pé, “Òmùgọ̀ ni wolii, aṣiwèrè sì ni ẹni tí ó wà ninu ẹ̀mí,” nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yín, ati ìkórìíra yín tí ó pọ̀.

8 Wolii ni aṣọ́nà fún Efuraimu, àwọn eniyan Ọlọrun mi, sibẹsibẹ tàkúté àwọn pẹyẹpẹyẹ wà lójú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ìkórìíra sì wà ní ilé Ọlọrun rẹ̀.

9 Wọ́n ti sọ ara wọn di aláìmọ́ lọpọlọpọ, bí ìgbà tí wọ́n wà ní Gibea. Ọlọrun yóo ranti àìdára tí wọ́n ṣe, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

10 OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn.

11 Ògo Efuraimu yóo fò lọ bí ẹyẹ, wọn kò ní lóyún, wọn kò ní bímọ, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ kò ní sọ ninu wọn!