1 Ọ̀rọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n, ọmọ Dafidi, Ọba Jerusalẹmu nìyí.
2 Asán ninu asán, bí ọ̀jọ̀gbọ́n ti wí, asán ninu asán, gbogbo rẹ̀ asán ni.
3 Èrè kí ni eniyan ń jẹ ninu gbogbo làálàá rẹ̀, tí ó ń ṣe nílé ayé?
4 Ìran kan ń kọjá lọ, òmíràn ń dé, ṣugbọn ayé wà títí laelae.
5 Oòrùn ń yọ, oòrùn ń wọ̀, ó sì ń yára pada sí ibi tí ó ti yọ wá.
6 Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúsù, ó sì ń yípo lọ sí ìhà àríwá. Yíyípo ni afẹ́fẹ́ ń yípo, a sì tún pada sí ibi tí ó ti wá.