1 Ṣọ́ra, nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọrun, ó sàn kí o lọ máa kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀ ju pé kí o lọ máa rúbọ bí àwọn aṣiwèrè tí ń ṣe, tí wọn kò sì mọ̀ pé nǹkan burúkú ni àwọn ń ṣe.
2 Má fi ẹnu rẹ sọ ìsọkúsọ, má sì kánjú sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọrun, nítorí Ọlọrun ń bẹ lọ́run ìwọ sì wà láyé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n.
3 Ọpọlọpọ àkóléyà ní ń mú kí eniyan máa lá àlákálàá, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni eniyan sì fi ń mọ òmùgọ̀.
4 Bí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Ọlọrun, má fi falẹ̀, tètè san án, nítorí kò ní inú dídùn sí àwọn òmùgọ̀.
5 Ó sàn kí o má jẹ́ ẹ̀jẹ́ rárá ju pé kí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí o má mú un ṣẹ lọ.