7 Nígbà tí àlá bá pọ̀ ọ̀rọ̀ náà yóo pọ̀. Ṣugbọn pataki ni pé, ǹjẹ́ o tilẹ̀ bẹ̀rù Ọlọrun?
8 Bí o bá wà ní agbègbè tí wọ́n ti ń pọ́n talaka lójú, tí kò sì sí ìdájọ́ òdodo ati ẹ̀tọ́, má jẹ́ kí èyí yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí ẹni tí ó ga ju ọ̀gá àgbà lọ ń ṣọ́ ọ̀gá àgbà. Ẹni tó tún ga ju àwọn náà lọ tún ń ṣọ́ gbogbo wọn.
9 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, anfaani ni ilẹ̀ tí à ń dáko sí jẹ́ fún ọba.
10 Kò sí iye tó lè tẹ́ ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ owó lọ́rùn; bákan náà ni ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọrọ̀, kò sí iye tí ó lè jẹ lérè tí yóo tẹ́ ẹ lọ́rùn. Asán ni èyí pẹlu.
11 Bí ọrọ̀ bá ti ń pọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn tí yóo máa lò ó yóo máa pọ̀ sí i. Kò sì sí èrè tí ọlọ́rọ̀ yìí ní ju pé ó fi ojú rí ọrọ̀ rẹ̀ lọ.
12 Oorun dídùn ni oorun alágbàṣe, kì báà yó, kì báà má yó; ṣugbọn ìrònú ọrọ̀ kì í jẹ́ kí ọlọ́rọ̀ sùn lóru.
13 Nǹkankan ń ṣẹlẹ̀, tí ó burú, tí mo ṣàkíyèsí láyé yìí, àwọn eniyan a máa kó ọrọ̀ jọ fún ìpalára ara wọn.