1 Mo tún rí nǹkankan tí ó burú nílé ayé. Ó sì wọ ọmọ eniyan lọ́rùn pupọ.
2 Ẹni tí Ọlọrun fún ní ọrọ̀, ohun ìní ati iyì, tí ó ní ohun gbogbo tí ó fẹ́; sibẹsibẹ Ọlọrun kò jẹ́ kí ó gbádùn rẹ̀, ṣugbọn àjèjì ni ó ń gbádùn rẹ̀. Asán ni èyí, ìpọ́njú ńlá sì ni.
3 Bí ẹnìkan bá bí ọgọrun-un ọmọ, tí ó sì gbé ọpọlọpọ ọdún láyé, ṣugbọn tí kò gbádùn àwọn ohun tí ó dára láyé, tí wọn kò sì sin òkú rẹ̀, ọmọ tí a bí lókùú sàn jù ú lọ.
4 Nítorí òkúmọ yìí wá sinu asán, ó sì pada sinu òkùnkùn. Òkùnkùn bo orúkọ rẹ̀, ẹnìkan kò sì ranti rẹ̀ mọ́.