Ìwé Oníwàásù 9:1-7 BM

1 Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo fi sọ́kàn. Mo yẹ gbogbo rẹ̀ wò, bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn olódodo, àwọn ọlọ́gbọ́n, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn wà. Bí ti ìfẹ́ ni, bí ti ìkórìíra ni, ẹnìkan kò mọ̀. Asán ni gbogbo ohun tí ó wà níwájú wọn.

2 Nítorí nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn: ati olódodo ati ẹlẹ́ṣẹ̀, ati eniyan rere ati eniyan burúkú, ati ẹni mímọ́, ati ẹni tí kò mọ́, ati ẹni tí ń rúbọ ati ẹni tí kì í rú. Bí eniyan rere ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹlẹ́ṣẹ̀ náà rí. Bákan náà ni ẹni tí ń búra ati ẹni tí ó takété sì ìbúra.

3 Nǹkankan tí ó burú, ninu àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé ni pé, ìpín kan náà ni gbogbo ọmọ aráyé ní, ọkàn gbogbo eniyan kún fún ibi, ìwà wèrè sì wà lọ́kàn wọn; lẹ́yìn náà, wọn a sì kú.

4 Ṣugbọn ìrètí ń bẹ fún ẹni tí ó wà láàyè, nítorí pé ààyè ajá wúlò ju òkú kinniun lọ.

5 Nítorí alààyè mọ̀ pé òun óo kú, ṣugbọn òkú kò mọ nǹkankan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní èrè kan mọ́, a kò sì ní ranti wọn mọ́.

6 Ìfẹ́, ati ìkórìíra, ati ìlara wọn ti parun, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ laelae ninu ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé.

7 Máa lọ fi tayọ̀tayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, sì máa mu ọtí waini rẹ pẹlu ìdùnnú, nítorí Ọlọrun ti fi ọwọ́ sí ohun tí ò ń ṣe.