9 Máa gbádùn ayé pẹlu aya rẹ, olólùfẹ́ rẹ, ní gbogbo ọjọ́ asán tí Ọlọrun fún ọ nílé ayé. Nítorí ìpín tìrẹ nìyí láyé ninu làálàá tí ò ń ṣe.
10 Ohunkohun tí o bá ti dáwọ́ lé, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é nítorí, kò sí iṣẹ́, tabi èrò, tabi ìmọ̀, tabi ọgbọ́n, ní isà òkú tí ò ń lọ.
11 Bákan náà, mo rí i pé, láyé, ẹni tí ó yára, tí ó lè sáré, lè má borí ninu eré ìje, alágbára lè jagun kó má ṣẹgun, ọlọ́gbọ́n lè má rí oúnjẹ jẹ, eniyan lè gbọ́n kó lóye, ṣugbọn kí ó má lówó lọ́wọ́, ẹni tí ó mọ iṣẹ́ ṣe sì lè má ní ìgbéga, àjálù ati èèṣì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni.
12 Kò sí ẹni tí ó mọ àkókò tirẹ̀. Bíi kí ẹja kó sinu àwọ̀n burúkú, tabi kí ẹyẹ kó sinu pańpẹ́, ni tàkúté ibi ṣe máa ń mú eniyan, nígbà tí àkókò ibi bá dé bá wọn.
13 Mo tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n kan nílé ayé, ó sì jẹ́ ohun ribiribi lójú mi.
14 Ìlú kékeré kan wà, tí eniyan kò pọ̀ ninu rẹ̀, ọba ńlá kan wà, ó dótì í, ó sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀.
15 Ọkunrin ọlọ́gbọ́n kan wà níbẹ̀ tí ó jẹ́ talaka, ó gba ìlú náà sílẹ̀ pẹlu ọgbọ́n rẹ̀, ṣugbọn ẹnìkan kò ranti talaka náà mọ́.