14 Mo dúpẹ́ pé n kò ṣe ìrìbọmi fún ẹnikẹ́ni ninu yín, àfi Kirisipu ati Gaiyu.
15 Kí ẹnikẹ́ni má baà wí pé orúkọ mi ni wọ́n fi ṣe ìrìbọmi fún òun.
16 Mo tún ranti! Mo ṣe ìrìbọmi fún ìdílé Stefana. N kò tún ranti ẹlòmíràn tí mo ṣe ìrìbọmi fún mọ́.
17 Nítorí pé Kristi kò fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrìbọmi rán mi, iṣẹ́ iwaasu ìyìn rere ni ó fi rán mi, kì í sìí ṣe nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, kí agbelebu Kristi má baà di òfo.
18 Nítorí ọ̀rọ̀ agbelebu Kristi jẹ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lójú àwọn tí ń ṣègbé. Ṣugbọn lójú àwọn tí à ń gbà là, agbára Ọlọrun ni.
19 Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Ọlọrun wí pé, ‘Èmi óo pa ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n run,n óo pa ìmọ̀ àwọn amòye tì sápá kan.’ ”
20 Ipò wo wá ni àwọn ọlọ́gbọ́n wà? Àwọn amòfin ńkọ́? Àwọn tí wọ́n mọ iyàn jà ní ayé yìí ńkọ́? Ṣebí Ọlọrun ti sọ ọgbọ́n ayé yìí di agọ̀!