33 Ẹ má jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ burúkú a máa ba ìwà rere jẹ́.
34 Ẹ ronú, kí ẹ sì máa ṣe dáradára. Ẹ má dẹ́ṣẹ̀ mọ́. Àwọn tí kò mọ Ọlọrun wà láàrin yín! Mò ń sọ èyí kí ojú kí ó lè tì yín ni.
35 Ṣugbọn ẹnìkan lè bèèrè pé, “Báwo ni a óo ti ṣe jí àwọn òkú dìde? Irú ara wo ni wọn óo ní?”
36 Ìwọ òmùgọ̀ yìí! Bí irúgbìn tí a bá gbìn kò bá kọ́ kú, kò lè hù.
37 Ohun tí ó bá hù kì í rí bí ohun tí a gbìn ti rí, nítorí pé irúgbìn lásán ni, ìbáà ṣe àgbàdo tabi àwọn ohun ọ̀gbìn yòókù.
38 Ọlọrun ni ó ń fún un ní ara tí ó bá fẹ́, a fún irúgbìn kọ̀ọ̀kan ní ara tirẹ̀.
39 Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe oríṣìí kan náà. Ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara eniyan, ọ̀tọ̀ ni ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ni ti ẹyẹ, ọ̀tọ̀ ni ti ẹja.