11 Títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ebi ń pa wá, òùngbẹ ń gbẹ wá, aṣọ sì di àkísà mọ́ wa lára. Wọ́n ń lù wá, a kò sì ní ibùgbé kan tààrà.
12 Àárẹ̀ mú wa bí a ti ń fi ọwọ́ ara wa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa. Àwọn eniyan ń bú wa, ṣugbọn àwa ń súre fún wọn. Wọ́n ń ṣe inúnibíni wa, ṣugbọn à ń fara dà á.
13 Wọ́n ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wa, ṣugbọn àwa ń sọ̀rọ̀ ìwúrí. A di ohun ẹ̀sín fún gbogbo ayé. A di pàǹtí fún gbogbo eniyan títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí.
14 Kì í ṣe pé mo fẹ́ dójú tì yín ni mo fi ń kọ nǹkan wọnyi si yín, mò ń kìlọ̀ fun yín gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ mi ni.
15 Nítorí pé, ẹ̀ báà ní ẹgbẹrun àwọn olùtọ́ ninu Kristi, ẹ kò ní ju ẹyọ baba kan lọ. Nítorí ninu Kristi Jesu, èmi ni mo bi yín nípa ọ̀rọ̀ ìyìn rere.
16 Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìwà jọ mí.
17 Ìdí tí mo ṣe rán Timoti si yín nìyí, ẹni tí ó jẹ́ àyànfẹ́ ọmọ fún mi, ati olóòótọ́ ninu nǹkan ti Oluwa. Òun ni yóo ran yín létí àwọn ohun tí mo fi ń ṣe ìwà hù ninu ìgbé-ayé titun ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu, gẹ́gẹ́ bí mo ti ń kọ́ gbogbo àwọn ìjọ níbi gbogbo.