5 Kí ojú baà lè tì yín ni mo fi ń sọ̀rọ̀ báyìí! Ṣé kò wá sí ẹnikẹ́ni láàrin yín tí ó gbọ́n tó láti dá ẹjọ́ fún ẹnìkan ati arakunrin rẹ̀ ni?
6 Dípò kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, onigbagbọ ń pe onigbagbọ lẹ́jọ́ níwájú àwọn alaigbagbọ!
7 Nǹkankan kù díẹ̀ kí ó tó nípa igbagbọ yín. Òun ni ó mú kí ẹ máa ní ẹ̀sùn sí ara yín. Kí ni kò jẹ́ kí olukuluku yín kúkú máa gba ìwọ̀sí? Kí ni kò jẹ́ kí ẹ máa gba ìrẹ́jẹ?
8 Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni ẹ̀ ń fi ìwọ̀sí kan ara yín tí ẹ̀ ń rẹ́ ara yín jẹ, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ onigbagbọ!
9 Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin;
10 àwọn olè tabi àwọn olójúkòkòrò, àwọn ọ̀mùtí-para tabi àwọn abanijẹ́, tabi àwọn oníjìbìtì, tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun.
11 Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.