54 Wọ́n bá mú Jesu, wọ́n fà á lọ sí ilé Olórí Alufaa. Ṣugbọn Peteru ń tẹ̀lé wọn lókèèrè.
55 Àwọn kan dá iná sáàrin agbo-ilé, wọ́n jókòó yí i ká, Peteru náà wà láàrin wọn.
56 Ọmọdebinrin kan wá rí i, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu.”
57 Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “N kò tilẹ̀ mọ ọkunrin yìí!”
58 Nígbà tí ó ṣe díẹ̀, ẹlòmíràn tún rí i, ó ní, “Ìwọ náà wà láàrin wọn.”Ṣugbọn Peteru ní, “Ọkunrin yìí, n kò sí níbẹ̀!”
59 Nígbà tí ó tó bíi wakati kan, ọkunrin kan tún sọ pẹlu ìdánilójú pé, “Láìsí àní-àní ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu, nítorí ará Galili ni.”
60 Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Ọkunrin yìí, n kò mọ ohun tí ò ń sọ!”Lẹsẹkẹsẹ, ó fẹ́rẹ̀ ma tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, àkùkọ bá kọ.