4 Yóo lòdì sí ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti Ọlọrun tabi tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn. Yóo gbé ara rẹ̀ ga ju èyíkéyìí ninu àwọn oriṣa lọ; yóo tilẹ̀ lọ jókòó ninu Tẹmpili Ọlọrun, yóo sì fi ara hàn pé òun ni Ọlọrun.
5 Ẹ ranti pé a ti sọ gbogbo èyí fun yín nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín.
6 Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ mọ ohun tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò, tí kò jẹ́ kí ó farahàn títí àkókò rẹ̀ yóo fi tó.
7 Nítorí nǹkan àṣírí kan tíí máa fa rúkèrúdò ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́, ṣugbọn ẹni tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò wà, kò ì kúrò lọ́nà.
8 Nígbà tí ó bá kúrò lọ́nà tán ni Ọkunrin Burúkú nnì yóo wá farahàn. Ṣugbọn Oluwa Jesu yóo fi èémí ẹnu rẹ̀ pa á, yóo sọ ìfarahàn rẹ̀ di asán.
9 Nítorí Ẹni Burúkú yìí yóo farahàn pẹlu agbára Èṣù: yóo máa pidán, yóo ṣe iṣẹ́ àmì, yóo ṣe iṣẹ́ ìtànjẹ tí ó yani lẹ́nu.
10 Yóo fi ọ̀nà àrékérekè burúkú lóríṣìíríṣìí tan àwọn ẹni ègbé jẹ, nítorí wọn kò ní ìfẹ́ òtítọ́, tí wọn ìbá fi rí ìgbàlà.