Tẹsalonika Kinni 2:12-18 BM

12 tí à ń gbà yín níyànjú, tí à ń rọ̀ yín, tí à ń kìlọ̀ fun yín nípa bí ó ti yẹ kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín bí ẹni tí Ọlọrun pè sinu ìjọba ati ògo rẹ̀.

13 Nítorí náà, àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo, nítorí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ẹ gbọ́ lẹ́nu wa, ẹ gbà á bí ó ti rí gan-an ni. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ẹ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ eniyan. Ọ̀rọ̀ náà sì ń ṣiṣẹ́ ninu ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́.

14 Nítorí, ẹ ti di aláfarawé àwọn ìjọ Ọlọrun tí ó wà ninu Kristi Jesu ní ilẹ̀ Judia, nítorí irú ìyà tí wọ́n jẹ lọ́wọ́ àwọn Juu ni ẹ̀yin náà jẹ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀yà tiyín.

15 Àwọn Juu yìí ni wọ́n pa Oluwa Jesu ati àwọn wolii, tí wọ́n sì fi inúnibíni lé wa jáde. Wọn kò ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun, wọ́n sì ń lòdì sí àwọn ohun tí ó lè ṣe eniyan ní anfaani.

16 Wọ́n ń ṣe ìdínà fún wa kí á má baà lè waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu, kí wọn má baà rí ìgbàlà, kí òṣùnwọ̀n ẹ̀ṣẹ̀ wọn baà lè kún. Ṣugbọn ibinu Ọlọrun ti dé sórí wọn.

17 Ẹ̀yin ará, nígbà tí a kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pínyà nípa ti ara, sibẹ ọkàn wa kò kúrò lọ́dọ̀ yín, ọkàn yín tún ń fà wá gan-an ni.

18 A fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀ẹ̀kan tabi ẹẹmeji ni èmi Paulu ti fẹ́ wá, ṣugbọn Satani dí wa lọ́wọ́.