1 O si ṣe lẹhin ikú Joṣua, ni awọn ọmọ Israeli bère lọdọ OLUWA wipe, Tani yio tète gòke tọ̀ awọn ara Kenaani lọ fun wa, lati bá wọn jà?
2 OLUWA si wipe, Juda ni yio gòke lọ: kiyesi i, emi fi ilẹ̀ na lé e lọwọ.
3 Juda si wi fun Simeoni arakunrin rẹ̀ pe, Bá mi gòke lọ si ilẹ mi, ki awa ki o le bá awọn ara Kenaani jà; emi na pẹlu yio si bá ọ lọ si ilẹ rẹ. Simeoni si bá a lọ.
4 Juda si gòke lọ; OLUWA si fi awọn ara Kenaani ati awọn Perissi lé wọn lọwọ: nwọn si pa ẹgbarun ọkunrin ninu wọn ni Beseki.
5 Nwọn si ri Adoni-beseki ni Beseki: nwọn si bá a jà, nwọn si pa awọn ara Kenaani ati awọn Perissi.