A. Oni 21 YCE

Àwọn Ẹ̀yà Bẹnjamini Fẹ́ Iyawo

1 AWỌN ọkunrin Israeli si ti bura ni Mispe, pe, Ẹnikan ninu wa ki yio fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Benjamini li aya.

2 Awọn enia na si wá si Beti-eli, nwọn si joko nibẹ̀ titi di aṣalẹ niwaju Ọlọrun, nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun gidigidi.

3 Nwọn si wipe, OLUWA, Ọlọrun Israeli, ẽṣe ti o fi ri bayi ni Israeli, ti ẹ̀ya kan fi bùku li oni ninu awọn enia Israeli?

4 O si ṣe ni ijọ́ keji, awọn enia na dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si mọ pẹpẹ kan nibẹ̀, nwọn si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia.

5 Awọn ọmọ Israeli si wipe, Tali o wà ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli ti kò bá ijọ gòke tọ̀ OLUWA wá? Nitoripe nwọn ti bura nla niti ẹniti kò ba tọ̀ OLUWA wá ni Mispe, wipe, Pipa li a o pa a.

6 Awọn ọmọ Israeli si kãnu nitori Benjamini arakunrin wọn, nwọn si wipe, A ke ẹ̀ya kan kuro ni Israeli li oni.

7 Awa o ha ti ṣe niti obinrin fun awọn ti o kù, awa sá ti fi OLUWA bura pe, awa ki yio fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn li aya.

8 Nwọn si wipe, Ewo ni ninu awọn ẹ̀ya Israeli ti kò tọ̀ OLUWA wá ni Mispe? Si kiyesi i, kò sí ẹnikan ni ibudó ti o ti Jabeṣi-gileadi wá si ijọ.

9 Nitori nigbati a kà awọn enia na, si kiyesi i, kò sí ẹnikan nibẹ̀ ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi.

10 Ijọ si rán ẹgbã mẹfa ọkunrin ninu awọn akọni sibẹ̀, nwọn si fi aṣẹ fun wọn pe, Ẹ lọ ẹ si fi oju idà kọlù awọn ara Jabeṣi-gileadi, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọ wẹrẹ.

11 Eyiyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: gbogbo ọkunrin, ati gbogbo obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin li ẹnyin o parun patapata.

12 Nwọn si ri irinwo wundia ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi, ti kò ti imọ̀ ọkunrin nipa ibadapọ̀: nwọn si mú wọn wá si ibudó ni Ṣilo, ti o wà ni ilẹ Kenaani.

13 Gbogbo ijọ si ranṣẹ lọ bá awọn ọmọ Benjamini ti o wà ninu okuta Rimmoni sọ̀rọ, nwọn si fi alafia lọ̀ wọn.

14 Benjamini si pada li akokò na; nwọn si fun wọn li obinrin ti nwọn dasi ninu awọn obinrin Jabeṣi-gileadi: ṣugbọn sibẹ̀ nwọn kò si kari wọn.

15 Awọn enia na si kãnu nitori Benjamini, nitoripe OLUWA ṣe àlàfo ninu awọn ẹ̀ya Israeli.

16 Nigbana li awọn àgba ijọ wipe, Kini awa o ṣe niti obinrin fun awọn iyokù, nitoripe a ti pa gbogbo awọn obinrin run kuro ni Benjamini?

17 Nwọn si wipe, Ilẹ-iní kan yio wà fun awọn ti o ti sálà ni Benjamini, ki ẹ̀ya kan ki o má ba parun kuro ni Israeli.

18 Ṣugbọn awa kò lè fi aya fun wọn ninu awọn ọmọbinrin wa: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti bura, wipe, Egún ni fun ẹniti o ba fi aya fun Benjamini.

19 Nwọn si wipe, Kiyesi i, ajọ OLUWA wà li ọdọdún ni Ṣilo ni ìha ariwa Beti-eli, ni ìha ìla-õrùn ti opópo ti o lọ soke lati Beti-eli lọ titi dé Ṣekemu, ati ni ìha gusù ti Lebona.

20 Nwọn si fi aṣẹ fun awọn ọmọ Benjamini wipe, Ẹ lọ ki ẹ si ba sinu ọgbà-àjara;

21 Ki ẹ si wò, si kiyesi i, bi awọn ọmọbinrin Ṣilo ba jade wá lati jó ninu ijó wọnni, nigbana ni ki ẹnyin ki o jade lati inu ọgbà-àjara wá, ki olukuluku ọkunrin nyin ki o si mú aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Ṣilo, ki ẹnyin ki o si lọ si ilẹ Benjamini.

22 Yio si ṣe, nigbati awọn baba wọn tabi awọn arakunrin wọn ba tọ̀ wa wá lati wijọ, awa o si wi fun wọn pe, Ẹ ṣãnu wọn nitori wa: nitoriti awa kò mú aya olukuluku fun u li ogun na: bẹ̃ni ki iṣe ẹnyin li o fi wọn fun wọn; nigbana ni ẹnyin iba jẹbi.

23 Awọn ọmọ Benjamini si ṣe bẹ̃, nwọn si mú aya, gẹgẹ bi iye wọn, ninu awọn ẹniti njó, awọn ti nwọn múlọ; nwọn si lọ nwọn pada si ilẹ-iní wọn nwọn si kọ ilu wọnni, nwọn si joko sinu wọn.

24 Nigbana li awọn ọmọ Israeli si lọ lati ibẹ̀, olukuluku enia si ẹ̀ya tirẹ̀, ati si idile tirẹ̀, nwọn si jade lati ibẹ̀ lọ olukuluku enia si ilẹ-iní tirẹ̀.

25 Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21