1 ANGELI OLUWA si ti Gilgali gòke wá si Bokimu. O si wipe, Emi mu nyin gòke lati Egipti wá, emi si mú nyin wá si ilẹ ti emi ti bura fun awọn baba nyin; emi si wipe, Emi ki yio dà majẹmu mi pẹlu nyin lailai:
2 Ẹnyin kò si gbọdọ bá awọn ara ilẹ yi dá majẹmu; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn lulẹ: ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn mi: Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi?
3 Nitorina emi pẹlu wipe, Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ ẹgún ni ìha nyin, ati awọn oriṣa wọn yio di ikẹkun fun nyin.
4 O si ṣe, nigbati angeli OLUWA sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, awọn enia na si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun.
5 Nwọn si pè orukọ ibẹ̀ na ni Bokimu: nwọn si ru ẹbọ nibẹ̀ si OLUWA.
6 Nigbati Joṣua si ti jọwọ awọn enia lọwọ lọ, olukuluku awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ilẹ-iní rẹ̀ lati gba ilẹ̀ na.
7 Awọn enia na si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, awọn ẹniti o ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA, ti o ṣe fun Israeli.
8 Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA si kú, nigbati o di ẹni ãdọfa ọdún.
9 Nwọn si sinkú rẹ̀ li àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnati-heresi, ni ilẹ òke Efraimu, li ariwa oke Gaaṣi.
10 Ati pẹlu a si kó gbogbo iran na jọ sọdọ awọn baba wọn: iran miran si hù lẹhin wọn, ti kò mọ̀ OLUWA, tabi iṣẹ ti o ṣe fun Israeli.
11 Awọn ọmọ Israeli si ṣe buburu niwaju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu:
12 Nwọn si kọ̀ OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nwọn si ntọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia ti o yi wọn ká kiri, nwọn si nfi ori wọn balẹ fun wọn, nwọn si bi OLUWA ninu.
13 Nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn si nsìn Baali ati Aṣtarotu.
14 Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si fi wọn lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrù, o si tà wọn si ọwọ́ awọn ọtá wọn yiká kiri, tobẹ̃ ti nwọn kò le duro mọ́ niwaju awọn ọtá wọn.
15 Nibikibi ti nwọn ba jade lọ, ọwọ́ OLUWA wà lara wọn fun buburu, gẹgẹ bi OLUWA ti wi, ati gẹgẹ bi OLUWA ti bura fun wọn: oju si pọ́n wọn pupọ̀pupọ̀.
16 OLUWA si gbé awọn onidajọ dide, ti o gbà wọn li ọwọ́ awọn ẹniti nkó wọn lẹrù.
17 Sibẹ̀sibẹ nwọn kò fetisi ti awọn onidajọ wọn, nitoriti nwọn ṣe panṣaga tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, nwọn si fi ori wọn balẹ fun wọn: nwọn yipada kánkan kuro li ọ̀na ti awọn baba wọn ti rìn, ni gbigbà ofin OLUWA gbọ́; awọn kò ṣe bẹ̃.
18 Nigbati OLUWA ba si gbé awọn onidajọ dide fun wọn, OLUWA a si wà pẹlu onidajọ na, on a si gbà wọn kuro li ọwọ́ awọn ọtá wọn ni gbogbo ọjọ́ onidajọ na: nitoriti OLUWA kãnu, nitori ikerora wọn nitori awọn ti npọ́n wọn loju, ti nwọn si nni wọn lara.
19 O si ṣe, nigbati onidajọ na ba kú, nwọn a si pada, nwọn a si bà ara wọn jẹ́ jù awọn baba wọn lọ, ni titọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma fi ori balẹ fun wọn; nwọn kò dẹkun iṣe wọn, ati ìwa-agidi wọn.
20 Ibinu OLUWA si rú si Israeli; o si wipe, Nitoriti orilẹ-ède yi ti re majẹmu mi kọja eyiti mo ti palaṣẹ fun awọn baba wọn, ti nwọn kò si gbọ́ ohùn mi;
21 Emi pẹlu ki yio lé ọkan jade mọ́ kuro niwaju wọn ninu awọn orilẹ-ède, ti Joṣua fisilẹ nigbati o kú:
22 Ki emi ki o le ma fi wọn dan Israeli wò, bi nwọn o ma ṣe akiyesi ọ̀na OLUWA lati ma rìn ninu rẹ̀, bi awọn baba wọn ti ṣe akiyesi rẹ̀, tabi bi nwọn ki yio ṣe e.
23 OLUWA si fi orilẹ-ède wọnni silẹ, li ailé wọn jade kánkan; bẹ̃ni kò si fi wọn lé Joṣua lọwọ.