A. Oni 16 YCE

Samsoni ní Ìlú Gasa

1 SAMSONI si lọ si Gasa, o si ri obinrin panṣaga kan nibẹ̀, o si wọle tọ̀ ọ.

2 Awọn ara Gasa si gbọ́ pe, Samsoni wá si ihin. Nwọn si yi i ká, nwọn lùmọ́ ni gbogbo oru na li ẹnu-bode ilu na, nwọn si dakẹ jẹ ni gbogbo oru na, wipe, Li owurọ̀ nigbati ilẹ ba mọ́, li awa a pa a.

3 Samsoni si dubulẹ titi o fi di ãrin ọganjọ, o si dide lãrin ọganjọ, o si gbé ilẹkun-ibode ilu na, ati opó mejeji, o si fà wọn tu pẹlu idabu-ilẹ̀kùn, o gbé wọn lé ejika rẹ̀, o si rù wọn lọ si ori òke kan ti o wà niwaju Hebroni.

Samsoni ati Delila

4 O si ṣe lẹhin eyinì, o si fẹ́ obinrin kan li afonifoji Soreki, a si ma pè orukọ rẹ̀ ni Delila.

5 Awọn ijoye Filistini tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Tàn a, ki o si mọ̀ ibiti agbara nla rẹ̀ gbé wà, ati bi awa o ti ṣe le bori rẹ̀, ki awa ki o le dè e lati jẹ ẹ niyà: olukuluku wa yio si fun ọ ni ẹdẹgbẹfa owo fadakà.

6 Delila si wi fun Samsoni pe, Emi bẹ̀ ọ, wi fun mi, nibo li agbara nla rẹ gbé wà, ati kili a le fi dè ọ lati jẹ ọ niyà.

7 Samsoni si wi fun u pe, Bi a ba fi okùn tutù meje ti a kò ságbẹ dè mi, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.

8 Nigbana li awọn ijoye Filistini mú okùn tutù meje tọ̀ ọ wá ti a kò ságbẹ, o si fi okùn wọnni dè e.

9 Obinrin na si ní awọn kan, ti nwọn lumọ́ ninu yará. On si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. On si já okùn na, gẹgẹ bi owú ti ijá nigbati o ba kan iná. Bẹ̃li a kò mọ̀ agbara rẹ̀.

10 Delila si wi fun Samsoni pe, Kiyesi i, iwọ tàn mi jẹ, o si purọ́ fun mi: wi fun mi, emi bẹ̀ ọ, kili a le fi dè ọ.

11 On si wi fun u pe, Bi nwọn ba le fi okùn titun ti a kò ti lò rí dè mi le koko, nigbana li emi o di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.

12 Bẹ̃ni Delila mú okùn titun, o si fi dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. Awọn ti o lumọ́ dè e wà ninu yará. On si já wọn kuro li apa rẹ̀ bi owu.

13 Delila si wi fun Samsoni pe, Titi di isisiyi iwọ ntàn mi ni, iwọ si npurọ́ fun mi: sọ fun mi, kili a le fi dè ọ. On si wi fun u pe, Bi iwọ ba wun ìdi irun meje ti o wà li ori mi.

14 On si fi ẽkàn dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju orun rẹ̀, o si fà ẽkàn ìti na pẹlu ihunṣọ rẹ̀ lọ.

15 On si wi fun u pe, Iwọ ha ti ṣe wipe, Emi fẹ́ ọ, nigbati ọkàn rẹ kò ṣedede pẹlu mi? iwọ ti tàn mi ni ìgba mẹta yi, iwọ kò si sọ ibiti agbara nla rẹ gbé wà fun mi.

16 O si ṣe, nigbati o fi ọ̀rọ rẹ̀ rọ̀ ọ li ojojumọ́, ti o si ṣe e laisimi, tobẹ̃ ti sũru fi tan ọkàn rẹ̀ dé ikú.

17 Li on si sọ gbogbo eyiti o wà li ọkàn rẹ̀ fun u, o si wi fun u pe, Abẹ kò kàn ori mi rí; nitoripe Nasiri Ọlọrun li emi iṣe lati inu iya mi wá: bi a ba fá ori mi, nigbana li agbara mi yio lọ kuro lọdọ mi, emi o si di alailera, emi o si dabi ọkunrin miran.

18 Nigbati Delila ri pe, o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun u, o si ranṣẹ pè awọn ijoye Filistini, wipe, Ẹ gòke wá lẹ̃kan yi, nitoriti o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun mi. Nigbana li awọn ijoye Filistini wá sọdọ rẹ̀, nwọn si mú owo li ọwọ́ wọn.

19 O si mú ki o sùn li ẽkun rẹ̀; o si pè ọkunrin kan, o si mu ki o fá ìdi irun mejeje ori rẹ̀; on si bẹ̀rẹsi pọ́n ọ loju, agbara rẹ̀ si ti lọ kuro lọdọ rẹ̀.

20 On si wipe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju õrun rẹ̀, o si wipe, Emi o jade lọ bi ìgba iṣaju, ki emi ki o si gbọ̀n ara mi. On kò si mọ̀ pe OLUWA ti kuro lọdọ on.

21 Awọn Filistini sì mú u, nwọn si yọ ọ li oju mejeji; nwọn si mú u sọkalẹ wá si Gasa, nwọn si fi ṣẹkẹṣẹkẹ̀ idẹ dè e: on si nlọ-ọlọ ni ile-tubu.

22 Ṣugbọn irun ori rẹ̀ bẹ̀rẹsi hù lẹhin igbati a ti fá a tán.

Ikú Samsoni

23 Nigbana ni awọn ijoye Filistini kó ara wọn jọ lati ru ẹbọ nla kan si Dagoni oriṣa wọn, ati lati yọ̀: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi Samsoni ọtá wa lé wa lọwọ.

24 Nigbati awọn enia si ri i, nwọn fi iyin fun oriṣa wọn: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi ọtá wa lé wa lọwọ, ẹniti npa ilẹ wa run, ti o si pa ọ̀pọlọpọ enia ninu wa.

25 O si ṣe, nigbati inu wọn dùn, ni nwọn wipe, Ẹ pè Samsoni, ki o wa ṣiré fun wa. Nwọn si pè Samsoni lati inu ile-itubu wá; o si ṣiré niwaju wọn: nwọn si mu u duro lãrin ọwọ̀n meji.

26 Samsoni si wi fun ọmọkunrin ti o di ọwọ́ rẹ̀ mú pe, Jẹ ki emi ki o fọwọbà awọn ọwọ̀n ti ile joko lé, ki emi ki o le faratì wọn.

27 Njẹ ile na kún fun ọkunrin ati obinrin; gbogbo awọn ijoye Filistini si wà nibẹ̀; awọn ti o si wà lori orule, ati ọkunrin ati obinrin, o to ìwọn ẹgbẹdogun enia, ti nworan Samsoni nigbati o nṣiré.

28 Samsoni si kepè OLUWA, o si wipe, Oluwa ỌLỌRUN, emi bẹ̀ ọ, ranti mi, ki o si jọ̃ fun mi li agbara lẹ̃kanṣoṣo yi, Ọlọrun, ki emi ki o le gbẹsan lẹ̃kan lara awọn Filistini nitori oju mi mejeji.

29 Samsoni si dì ọwọ̀n ãrin mejeji na mú lori eyiti ile na joko, o si faratì wọn, o fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ mú kan, o si fi ọwọ́ òsi rẹ̀ mú ekeji.

30 Samsoni si wipe, Jẹ ki nkú pẹlu awọn Filistini. O si fi gbogbo agbara rẹ̀ bẹ̀rẹ; ile na si wó lù awọn ijoye wọnni, ati gbogbo enia ti o wà ninu rẹ̀. Bẹ̃li awọn okú ti o pa ni ikú rẹ̀, pọjù awọn ti o pa li ãyè rẹ̀ lọ.

31 Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo idile baba rẹ̀ sọkalẹ wá, nwọn si gbé e gòke, nwọn si sin i lãrin Sora on Eṣtaolu ni ibojì Manoa baba rẹ̀. O si ṣe idajọ Israeli li ogún ọdún.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21