1 O SI ṣe lẹhin ìgba diẹ, li akokò ikore alikama, Samsoni mú ọmọ ewurẹ kan lọ bẹ̀ aya rẹ̀ wò; on si wipe, Emi o wọle tọ̀ aya mi lọ ni iyẹwu. Ṣugbọn baba obinrin rẹ̀ kò jẹ ki o wọle.
2 Baba aya rẹ̀ si wipe, Nitõtọ emi ṣebi iwọ korira rẹ̀ patapata ni; nitorina ni mo ṣe fi i fun ẹgbẹ rẹ: aburò rẹ̀ kò ha ṣe arẹwà enia jù on lọ? mo bẹ̀ ọ, mú u dipò rẹ̀.
3 Samsoni si wi fun wọn pe, Nisisiyi emi o jẹ́ alaijẹbi lọdọ awọn Filistini, bi mo tilẹ ṣe wọn ni ibi.
4 Samsoni si lọ o mú ọdunrun kọ̀lọkọlọ, o si mú ètufu, o si fi ìru wọn kò ìru, o si fi ètufu kan sãrin ìru meji.
5 Nigbati o si ti fi iná si ètufu na, o jọwọ wọn lọ sinu oko-ọkà awọn Filistini, o si kun ati eyiti a dì ni ití, ati eyiti o wà li oró, ati ọgbà-olifi pẹlu.
6 Nigbana li awọn Filistini wipe, Tani ṣe eyi? Nwọn si dahùn pe, Samsoni, ana ara Timna ni, nitoriti o gbà obinrin rẹ̀, o si fi i fun ẹgbẹ rẹ̀. Awọn Filistini si gòke wá, nwọn si fi iná sun obinrin na ati baba rẹ̀.
7 Samsoni si wi fun wọn pe, Bi ẹnyin ba ṣe irú eyi, dajudaju emi o gbẹsan lara nyin, lẹhin na emi o si dẹkun.
8 On si kọlù wọn, o si pa wọn ni ipakupa: o si sọkalẹ o si joko ni pàlàpálá apata Etamu.
9 Nigbana li awọn Filistini gòke lọ, nwọn si dótì Juda, nwọn si tẹ́ ara wọn lọ bẹrẹ ni Lehi.
10 Awọn ọkunrin Juda si wipe, Nitori kili ẹnyin ṣe gòke tọ̀ wa wá? Nwọn si dahùn wipe, Lati dè Samsoni li awa ṣe wá, lati ṣe si i gẹgẹ bi on ti ṣe si wa.
11 Nigbana li ẹgbẹdogun ọkunrin Juda sọkalẹ lọ si palapala apata Etamu, nwọn si wi fun Samsoni, pe, Iwọ kò mọ̀ pe awọn Filistini li alaṣẹ lori wa? kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? On si wi fun wọn pe, Gẹgẹ bi nwọn ti ṣe si mi, bẹ̃li emi ṣe si wọn.
12 Nwọn si wi fun u pe, Awa sọkalẹ wá lati dè ọ, ki awa ki o le fi ọ lé awọn Filistini lọwọ. Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ bura fun mi, pe ẹnyin tikara nyin ki yio pa mi.
13 Nwọn si wi fun u pe, Rárá o; didè li awa o dè ọ, a o si fi ọ lé wọn lọwọ: ṣugbọn niti pipa awa ki yio pa ọ. Nwọn si fi okùn titun meji dè e, nwọn si mú u gòke lati ibi apata na wá.
14 Nigbati o dé Lehi, awọn Filistini hó bò o: ẹmi OLUWA si bà lé e, okùn ti o si wà li apa rẹ̀ si wa dabi okùn-ọ̀gbọ ti o ti jóna, ìde rẹ̀ si tú kuro li ọwọ́ rẹ̀.
15 O si ri pari-ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ titun kan, o si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si fi i pa ẹgbẹrun ọkunrin.
16 Samsoni si wipe, Pari-ẹrẹkẹ kan ni mo fi pa òkiti kan, òkiti meji; pari-ẹrẹkẹ kẹtẹkẹtẹ kan ni mo fi pa ẹgbẹrun ọkunrin.
17 O si ṣe, nigbati o pari ọ̀rọ isọ tán, o sọ pari-ẹrẹkẹ na nù, o si pè ibẹ̀ na ni Ramati-lehi.
18 Ongbẹ si ngbẹ ẹ gidigidi, o si kepè OLUWA, wipe, Iwọ ti fi ìgbala nla yi lé ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ: nisisiyi emi o kú nitori ongbẹ, emi o si bọ́ si ọwọ́ awọn alaikọlà.
19 Ṣugbọn Ọlọrun si là ibi kòto kan ti o wà ni Lehi, nibẹ̀ li omi si sun jade; nigbati on si mu u tán ẹmi rẹ̀ si tun pada, o si sọjí: nitorina ni a ṣe pè orukọ ibẹ̀ na ni Eni-hakkore, ti o wà ni Lehi, titi o fi di oni-oloni.
20 On si ṣe idajọ Israeli li ọjọ́ awọn Filistini li ogún ọdún.