2 OLUWA si wipe, Juda ni yio gòke lọ: kiyesi i, emi fi ilẹ̀ na lé e lọwọ.
3 Juda si wi fun Simeoni arakunrin rẹ̀ pe, Bá mi gòke lọ si ilẹ mi, ki awa ki o le bá awọn ara Kenaani jà; emi na pẹlu yio si bá ọ lọ si ilẹ rẹ. Simeoni si bá a lọ.
4 Juda si gòke lọ; OLUWA si fi awọn ara Kenaani ati awọn Perissi lé wọn lọwọ: nwọn si pa ẹgbarun ọkunrin ninu wọn ni Beseki.
5 Nwọn si ri Adoni-beseki ni Beseki: nwọn si bá a jà, nwọn si pa awọn ara Kenaani ati awọn Perissi.
6 Ṣugbọn Adoni-beseki sá; nwọn si lepa rẹ̀, nwọn si mú u, nwọn si ke àtampako ọwọ́ rẹ̀, ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀.
7 Adoni-beseki si wipe, Adọrin ọba li emi ke li àtampako ọwọ́ wọn ati ti ẹsẹ̀ wọn, ti nwọn nṣà onjẹ wọn labẹ tabili mi: gẹgẹ bi emi ti ṣe, bẹ̃li Ọlọrun si san a fun mi. Nwọn si mú u wá si Jerusalemu, o si kú sibẹ̀.
8 Awọn ọmọ Juda si bá Jerusalemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si tinabọ ilu na.