1 JEFTA ara Gileadi si jẹ́ akọni ọkunrin, on si jẹ́ ọmọ panṣaga obinrin kan: Gileadi si bi Jefta.
2 Aya Gileadi si bi awọn ọmọkunrin fun u; nigbati awọn ọmọ aya na si dàgba, nwọn si lé Jefta jade, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ki yio jogún ni ile baba wa; nitoripe ọmọ ajeji obinrin ni iwọ iṣe.
3 Nigbana ni Jefta sá kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, on si joko ni ile Tobu: awọn enia lasan si kó ara wọn jọ sọdọ Jefta, nwọn si bá a jade lọ,
4 O si ṣe lẹhin ijọ́ melokan, awọn ọmọ Ammoni bá Israeli jagun.