25 Njẹ iwọ ha san jù Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu? on ha bá Israeli ṣe gbolohùn asọ̀ rí, tabi o ha bá wọn jà rí?
26 Nigbati Israeli fi joko ni Heṣboni ati awọn ilu rẹ̀, ati ni Aroeri ati awọn ilu rẹ̀, ati ni gbogbo awọn ilu ti o wà lọ titi de ẹba Arnoni, li ọdunrun ọdún; ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a li akokò na?
27 Nitorina emi kò ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ li o ṣẹ̀ mi ni bibá mi jà: ki OLUWA, Onidajọ, ki o ṣe idajọ li oni lãrin awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Ammoni.
28 Ṣugbọn ọba awọn ọmọ Ammoni kò fetisi ọ̀rọ Jefta, ti o rán si i.
29 Nigbana li ẹmi OLUWA bà lé Jefta, on si kọja Gileadi ati Manasse, o si kọja Mispa ti Gileadi, ati lati Mispa ti Gileadi o si kọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni.
30 Jefta si jẹ́ ẹjẹ́ fun Ọlọrun, o si wi pe, Bi iwọ ba jẹ fi awọn ọmọ Ammoni lé mi lọwọ,
31 Yio si ṣe, ohunkohun ti o ba ti oju-ilẹkun ile mi wá ipade mi, nigbati emi ba ti ọdọ awọn Ammoni pada bọ̀ li alafia, ti OLUWA ni yio jẹ́, emi o si fi i ru ẹbọ sisun.