5 Awọn ara Gileadi si gbà iwọdo Jordani ṣiwaju Efraimu: o si ṣe, nigbati awọn isansa Efraimu ba wipe, Jẹ ki emi ki o rekọja, awọn ọkunrin Gileadi a si wi fun u pe, Efraimu ki iwọ iṣe? Bi on ba si wipe, Rárá o!
6 Nwọn a si wi fun u pe, Njẹ wi pe Ṣibboleti; on si wi pe Sibboleti, nitoripe on kò le pè e rere; nwọn a si mú u, nwọn a si pa a si iwọdo Jordani: awọn ti o si ṣubu li akokò na ninu awọn Efraimu jẹ́ ẹgbã mọkanlelogun enia.
7 Jefta si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹfa. Jefta ara Gileadi si kú, a si sin i si ọ̀kan ninu awọn ilú Gileadi.
8 Lẹhin rẹ̀ ni Ibsani ara Beti-lehemu ṣe idajọ Israeli.
9 O si lí ọgbọ̀n ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọbinrin ti on rán lọ si ode, o si fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin lati ode wá fi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀. On si ṣe idajọ Israeli li ọdún meje.
10 Ibsani si kú, a si sin i ni Beti-lehemu.
11 Lẹhin rẹ̀ ni Eloni ti ẹ̀ya Sebuluni ṣe idajọ Israeli; on si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹwa.