1 AWỌN ọmọ Israeli si tun ṣe eyiti iṣe buburu li oju OLUWA; OLUWA si fi wọn lé awọn Filistini li ọwọ́ li ogoji ọdún.
2 Ọkunrin kan ara Sora si wà, ti iṣe idile Dani, orukọ rẹ̀ si ni Manoa, obinrin rẹ̀ si yàgan, kò si bimọ.
3 Angeli OLUWA si farahàn obinrin na, o si wi fun u pe, Sá kiyesi i, iwọ yàgan, iwọ kò si bimọ: ṣugbọn iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan.
4 Njẹ nitorina kiyesara, emi bẹ̀ ọ, máṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, má si ṣe jẹ ohun aimọ́ kan:
5 Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini.