22 Manoa si wi fun aya rẹ̀ pe, Kikú li awa o kú yi, nitoriti awa ti ri Ọlọrun.
23 Aya rẹ̀ si wi fun u pe, Ibaṣepe o wù OLUWA lati pa wa, on kì ba ti gbà ẹbọ sisun ati ẹbọ ohunjijẹ li ọwọ́ wa, bẹ̃li on kì ba ti fi gbogbo nkan wọnyi hàn wa, bẹ̃li on kì ba ti sọ̀rọ irú nkan wọnyi fun wa li akokò yi.
24 Obinrin na si bi ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Samsoni: ọmọ na si dàgba, OLUWA si bukún u.
25 Ẹmi OLUWA si bẹ̀rẹsi ṣiṣẹ ninu rẹ̀ ni Mahane-dani, li agbedemeji Sora ati Eṣtaolu.