1 SAMSONI si sọkalẹ lọ si Timna, o si ri obinrin kan ni Timna ọkan ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini.
2 O si gòke wá, o si sọ fun baba on iya rẹ̀, o si wipe, Emi ri obinrin kan ni Timna ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini: njẹ nitorina ẹ fẹ́ ẹ fun mi li aya.
3 Nigbana ni baba on iya rẹ̀ wi fun u pe, Kò sí obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin awọn arakunrin rẹ, tabi ninu gbogbo awọn enia mi, ti iwọ fi nlọ ní obinrin ninu awọn alaikọlà Filistini? Samsoni si wi fun baba rẹ̀ pe, Fẹ́ ẹ fun mi; nitoripe o wù mi gidigidi.
4 Ṣugbọn baba ati iya rẹ̀ kò mọ̀ pe ati ọwọ́ OLUWA wá ni, nitoripe on nwá ọ̀na lati bá awọn Filistini jà. Nitoripe li akokò na awọn Filistini li alaṣẹ ni Israeli.
5 Nigbana ni Samsoni sọkalẹ lọ si Timna, ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀, o si dé ibi ọgbà-àjara ti o wà ni Timna: si kiyesi i, ẹgbọrọ kiniun kan nke ramuramu si i.
6 Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si fà a ya bi iba ti fà ọmọ-ewurẹ ya, bẹ̃ni kò sí nkan li ọwọ́ rẹ̀: on kò si sọ fun baba tabi iya rẹ̀ li ohun ti o ṣe.