10 Baba rẹ̀ si sọkalẹ tọ̀ obinrin na lọ: Samsoni si sè àse nibẹ̀; nitoripe bẹ̃li awọn ọmọkunrin ima ṣe.
11 O si ṣe nigbati nwọn ri i, nwọn si mú ọgbọ̀n enia wa bá a kẹgbẹ.
12 Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki npa alọ́ kan fun nyin: bi ẹnyin ba le já a fun mi titi ijọ́ meje àse yi, ti ẹnyin ba si mọ̀ ọ, njẹ emi o fun nyin li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ:
13 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba le já a fun mi, njẹ ẹnyin o fun mi li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ. Nwọn si wi fun u pe, Pa alọ́ rẹ ki awa ki o gbọ́.
14 O si wi fun wọn pe, Lati inu ọjẹun li onjẹ ti jade wá, ati lati inu alagbara li adùn ti jade wá. Nwọn kò si le já alọ́ na nìwọn ijọ́ mẹta.
15 O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn si wi fun obinrin Samsoni pe, Tàn ọkọ rẹ, ki o le já alọ́ na fun wa, ki awa ki o má ba fi iná sun iwọ ati ile baba rẹ: ẹnyin pè wa ki ẹnyin ki o le gbà ohun-iní wa ni? bẹ̃ ha kọ?
16 Obinrin Samsoni si sọkun niwaju rẹ̀, o si wipe, Iwọ korira mi ni, iwọ kò si fẹràn mi: iwọ pa alọ́ kan fun awọn ọmọ enia mi, iwọ kò si já a fun mi. On si wi fun u pe, Kiyesi i, emi kò já a fun baba ati iya mi, emi o ha já a fun ọ bi?