13 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba le já a fun mi, njẹ ẹnyin o fun mi li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ. Nwọn si wi fun u pe, Pa alọ́ rẹ ki awa ki o gbọ́.
14 O si wi fun wọn pe, Lati inu ọjẹun li onjẹ ti jade wá, ati lati inu alagbara li adùn ti jade wá. Nwọn kò si le já alọ́ na nìwọn ijọ́ mẹta.
15 O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn si wi fun obinrin Samsoni pe, Tàn ọkọ rẹ, ki o le já alọ́ na fun wa, ki awa ki o má ba fi iná sun iwọ ati ile baba rẹ: ẹnyin pè wa ki ẹnyin ki o le gbà ohun-iní wa ni? bẹ̃ ha kọ?
16 Obinrin Samsoni si sọkun niwaju rẹ̀, o si wipe, Iwọ korira mi ni, iwọ kò si fẹràn mi: iwọ pa alọ́ kan fun awọn ọmọ enia mi, iwọ kò si já a fun mi. On si wi fun u pe, Kiyesi i, emi kò já a fun baba ati iya mi, emi o ha já a fun ọ bi?
17 O si sọkun niwaju rẹ̀ titi ijọ́ meje ti àse na gbà: O si ṣe ni ijọ́ keje, o si já a fun u, nitoripe on ṣe e li aisimi pupọ̀, on si já alọ́ na fun awọn ọmọ enia rẹ̀.
18 Awọn ọkunrin ilunla na si wi fun u ni ijọ́ keje ki õrùn ki o to wọ̀ pe, Kili o dùn jù oyin lọ? kili o si lí agbara jù kiniun lọ? On si wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin kò fi ẹgbọrọ abo-malu mi tulẹ, ẹnyin kì ba ti mọ̀ alọ́ mi.
19 Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si sọkalẹ lọ si Aṣkeloni, o si pa ọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn, o si kò ẹrù wọn, o si fi ìparọ aṣọ fun awọn ti o já alọ́ na. Ibinu rẹ̀ si rú, on si gòke lọ si ile baba rẹ̀.