5 Nigbana ni Samsoni sọkalẹ lọ si Timna, ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀, o si dé ibi ọgbà-àjara ti o wà ni Timna: si kiyesi i, ẹgbọrọ kiniun kan nke ramuramu si i.
6 Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si fà a ya bi iba ti fà ọmọ-ewurẹ ya, bẹ̃ni kò sí nkan li ọwọ́ rẹ̀: on kò si sọ fun baba tabi iya rẹ̀ li ohun ti o ṣe.
7 On si sọkalẹ lọ, o si bá obinrin na sọ̀rọ; on si wù Samsoni gidigidi.
8 Lẹhin ijọ́ melokan o si tun pada lati mú obinrin na, o si yà lati wò okú kiniun na: si kiyesi i, ìṣu-ọ̀pọ oyin wà ninu okú kiniun na, ati oyin.
9 O si bù ninu rẹ̀ si ọwọ́ rẹ̀, o si njẹ ẹ li ajẹrìn, titi o si fi dé ọdọ baba ati iya rẹ̀, o si fi fun wọn, nwọn si jẹ: ṣugbọn on kò sọ fun wọn pe ninu okú kiniun li on ti mú oyin na wá.
10 Baba rẹ̀ si sọkalẹ tọ̀ obinrin na lọ: Samsoni si sè àse nibẹ̀; nitoripe bẹ̃li awọn ọmọkunrin ima ṣe.
11 O si ṣe nigbati nwọn ri i, nwọn si mú ọgbọ̀n enia wa bá a kẹgbẹ.