1 O SI ṣe lẹhin ìgba diẹ, li akokò ikore alikama, Samsoni mú ọmọ ewurẹ kan lọ bẹ̀ aya rẹ̀ wò; on si wipe, Emi o wọle tọ̀ aya mi lọ ni iyẹwu. Ṣugbọn baba obinrin rẹ̀ kò jẹ ki o wọle.
2 Baba aya rẹ̀ si wipe, Nitõtọ emi ṣebi iwọ korira rẹ̀ patapata ni; nitorina ni mo ṣe fi i fun ẹgbẹ rẹ: aburò rẹ̀ kò ha ṣe arẹwà enia jù on lọ? mo bẹ̀ ọ, mú u dipò rẹ̀.
3 Samsoni si wi fun wọn pe, Nisisiyi emi o jẹ́ alaijẹbi lọdọ awọn Filistini, bi mo tilẹ ṣe wọn ni ibi.
4 Samsoni si lọ o mú ọdunrun kọ̀lọkọlọ, o si mú ètufu, o si fi ìru wọn kò ìru, o si fi ètufu kan sãrin ìru meji.