1 ỌKUNRIN kan si wà ni ilẹ òke Efraimu, orukọ ẹniti ijẹ Mika.
2 On si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẹdẹgbẹfa owo fadakà ti a kólọ lọwọ rẹ, nitori eyiti iwọ gegún, ti iwọ si sọ̀rọ rẹ̀ li etí mi pẹlu, kiyesi i, fadakà na wà li ọwọ́ mi; emi li o kó o. Iya rẹ̀ si wipe, Alabukún ti OLUWA ni ọmọ mi.
3 On si kó ẹdẹgbẹfa owo fadakà na fun iya rẹ̀ pada, iya rẹ̀ si wipe, Patapata ni mo yà fadakà wọnni sọ̀tọ fun OLUWA kuro li ọwọ́ mi, fun ọmọ mi, lati fi ṣe ere fifin ati ere didà: njẹ nitorina emi o fun ọ pada.
4 Ṣugbọn o kó owo na pada fun iya rẹ̀; iya rẹ̀ si mú igba owo fadakà, o si fi i fun oniṣọnà, ẹniti o fi i ṣe ere fifin ati ere didà: o si wà ni ile Mika.