28 Kò si sí olugbala, nitoriti o jìna si Sidoni, nwọn kò si bá ẹnikẹni ṣe; o si wà ni afonifoji ti o wà ni Beti-rehobu. Nwọn si kọ́ ilu na, nwọn si ngbé inu rẹ̀.
29 Nwọn si pè orukọ ilu na ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn, ẹniti a bi fun Israeli: ṣugbọn Laiṣi li orukọ ilu na li atijọ rí.
30 Awọn ọmọ Dani si gbé ere fifin na kalẹ: ati Jonatani, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, on ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin li o nṣe alufa fun ẹ̀ya Dani titi o fi di ọjọ́ ti a fi kó ilẹ na ni igbekun lọ.
31 Nwọn si gbé ere fifin ti Mika ṣe kalẹ ni gbogbo ọjọ́ ti ile Ọlọrun fi wà ni Ṣilo.