8 Nwọn si wá sọdọ awọn arakunrin wọn si Sora ati Eṣtaolu: awọn arakunrin wọn si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin wi?
9 Nwọn si wipe, Ẹ dide, ki awa ki o tọ̀ wọn: nitoriti awa ri ilẹ na, si kiyesi i, o dara gidigidi: ẹ dakẹ ni? ẹ má ṣe lọra lati lọ, ati lati wọ̀ ibẹ̀ lọ gbà ilẹ na.
10 Nigbati ẹnyin ba lọ, ẹnyin o dé ọdọ awọn enia ti o wà laibẹ̀ru, ilẹ na si tobi: nitoriti Ọlọrun ti fi i lé nyin lọwọ; ibiti kò sí ainí ohunkohun ti mbẹ lori ilẹ.
11 Awọn enia idile Dani si ti ibẹ̀ lọ, lati Sora ati lati Eṣtaolu, ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun;
12 Nwọn si gòke lọ, nwọn si dó si Kiriati-jearimu, ni Juda: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ̀ na ni Mahane-dani titi o fi di oni yi: kiyesi i, o wà lẹhin Kiriati-jearimu.
13 Nwọn si kọja lati ibẹ̀ lọ si ilẹ òke Efraimu, nwọn si wá si ile Mika.
14 Nigbana li awọn ọkunrin marun ti a rán ti o ti lọ ṣe amí ilẹ Laiṣi dahùn, nwọn si wi fun awọn arakunrin wọn pe, Ẹ mọ̀ pe efodu kan wà ninu ile wọnyi, ati terafimu, ati ere fifin, ati ere didà? njẹ nitorina ẹ rò eyiti ẹnyin o ṣe.