11 Nigbati nwọn si dé eti Jebusi, ọjọ́ lọ tán; ọmọ-ọdọ na si wi fun oluwa rẹ̀ pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a yà si ilu Jebusi yi, ki a si wọ̀ sibẹ̀.
12 Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, Awa ki o yà si ilu ajeji kan, ti ki iṣe ti awọn ọmọ Israeli; awa o rekọja si Gibea.
13 On si wi fun ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Wá jẹ ki a sunmọ ọkan ninu ibi wọnyi; ki a si wọ̀ si Gibea, tabi Rama.
14 Nwọn si rekọja, nwọn lọ: õrùn si wọ̀ bá wọn leti Gibea, ti iṣe ti Benjamini.
15 Nwọn si yà si Gibea lati wọ̀ ọ, ati lati sùn nibẹ̀: o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, o joko ni igboro ilu na: nitoriti kò sí ẹnikan ti o gbà wọn sinu ile rẹ̀ lati wọ̀.
16 Si kiyesi, i ọkunrin arugbo kan si nti ibi iṣẹ rẹ̀ bọ̀ lati inu oko wá li alẹ; ọkunrin na jẹ́ ara ilẹ òke Efraimu pẹlu, on si ṣe atipo ni Gibea: ṣugbọn ẹ̀ya Benjamini ni awọn ọkunrin ibẹ̀ iṣe.
17 Nigbati o gbé oju rẹ̀ soke, o si ri èro kan ni igboro ilu; ọkunrin arugbo na si wipe, Nibo ni iwọ nrè? nibo ni iwọ si ti wá?