15 Nwọn si yà si Gibea lati wọ̀ ọ, ati lati sùn nibẹ̀: o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, o joko ni igboro ilu na: nitoriti kò sí ẹnikan ti o gbà wọn sinu ile rẹ̀ lati wọ̀.
16 Si kiyesi, i ọkunrin arugbo kan si nti ibi iṣẹ rẹ̀ bọ̀ lati inu oko wá li alẹ; ọkunrin na jẹ́ ara ilẹ òke Efraimu pẹlu, on si ṣe atipo ni Gibea: ṣugbọn ẹ̀ya Benjamini ni awọn ọkunrin ibẹ̀ iṣe.
17 Nigbati o gbé oju rẹ̀ soke, o si ri èro kan ni igboro ilu; ọkunrin arugbo na si wipe, Nibo ni iwọ nrè? nibo ni iwọ si ti wá?
18 On si wi fun u pe, Awa nrekọja lati Beti-lehemu-juda lọ si ìha ọhùn ilẹ òke Efraimu; lati ibẹ̀ li emi ti wá, emi si ti lọ si Beti-lehemu-juda: nisisiyi emi nlọ si ile OLUWA; kò si sí ẹnikan ti o gbà mi si ile.
19 Bẹ̃ni koriko ati ohunjijẹ mbẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ wa; onjẹ ati ọti-waini si mbẹ fun mi pẹlu, ati fun iranṣẹbinrin rẹ, ati fun ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ awọn iranṣẹ rẹ: kò si sí ainí ohunkohun.
20 Ọkunrin arugbo na si wipe, Alafia fun ọ; bi o ti wù ki o ri, jẹ ki gbogbo ainí rẹ ki o pọ̀ si apa ọdọ mi; ọkanṣoṣo ni, máṣe sùn si igboro.
21 Bẹ̃li o mú u wá sinu ile rẹ̀, o si fi onjẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ: nwọn wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, nwọn jẹ nwọn si mu.