A. Oni 19:18-24 YCE

18 On si wi fun u pe, Awa nrekọja lati Beti-lehemu-juda lọ si ìha ọhùn ilẹ òke Efraimu; lati ibẹ̀ li emi ti wá, emi si ti lọ si Beti-lehemu-juda: nisisiyi emi nlọ si ile OLUWA; kò si sí ẹnikan ti o gbà mi si ile.

19 Bẹ̃ni koriko ati ohunjijẹ mbẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ wa; onjẹ ati ọti-waini si mbẹ fun mi pẹlu, ati fun iranṣẹbinrin rẹ, ati fun ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ awọn iranṣẹ rẹ: kò si sí ainí ohunkohun.

20 Ọkunrin arugbo na si wipe, Alafia fun ọ; bi o ti wù ki o ri, jẹ ki gbogbo ainí rẹ ki o pọ̀ si apa ọdọ mi; ọkanṣoṣo ni, máṣe sùn si igboro.

21 Bẹ̃li o mú u wá sinu ile rẹ̀, o si fi onjẹ fun awọn kẹtẹkẹtẹ: nwọn wẹ̀ ẹsẹ̀ wọn, nwọn jẹ nwọn si mu.

22 Njẹ bi nwọn ti nṣe ariya, kiyesi i, awọn ọkunrin ilu na, awọn ọmọ Beliali kan, yi ile na ká, nwọn si nlù ilẹkun; nwọn si sọ fun bale ile na ọkunrin arugbo nì, pe, Mú ọkunrin ti o wọ̀ sinu ile rẹ nì wá, ki awa ki o le mọ̀ ọ.

23 Ọkunrin, bale ile na si jade tọ̀ wọn lọ, o si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ẹnyin arakunrin mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ má ṣe hùwa buburu; nitoriti ọkunrin yi ti wọ̀ ile mi, ẹ má ṣe hùwa wère yi.

24 Kiyesi i, ọmọbinrin mi li eyi, wundia, ati àle rẹ̀; awọn li emi o mú jade wá nisisiyi, ki ẹnyin tẹ́ wọn li ogo, ki ẹnyin ṣe si wọn bi o ti tọ́ li oju nyin: ṣugbọn ọkunrin yi ni ki ẹnyin má ṣe hùwa wère yi si.