A. Oni 19:23-29 YCE

23 Ọkunrin, bale ile na si jade tọ̀ wọn lọ, o si wi fun wọn pe, Bẹ̃kọ, ẹnyin arakunrin mi, emi bẹ̀ nyin, ẹ má ṣe hùwa buburu; nitoriti ọkunrin yi ti wọ̀ ile mi, ẹ má ṣe hùwa wère yi.

24 Kiyesi i, ọmọbinrin mi li eyi, wundia, ati àle rẹ̀; awọn li emi o mú jade wá nisisiyi, ki ẹnyin tẹ́ wọn li ogo, ki ẹnyin ṣe si wọn bi o ti tọ́ li oju nyin: ṣugbọn ọkunrin yi ni ki ẹnyin má ṣe hùwa wère yi si.

25 Ṣugbọn awọn ọkunrin na kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀: ọkunrin na si mú àle rẹ̀, o si mú u tọ̀ wọn wá; nwọn si mọ̀ ọ, nwọn si hù u niwakiwa ni gbogbo oru na, titi o fi di owurọ̀: nigbati o si di afẹmọjumọ́ nwọn jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.

26 Nigbana li obinrin na wá li àfẹmọjumọ́, o si ṣubu lulẹ, li ẹnu-ilẹkun ile ọkunrin na nibiti oluwa rẹ̀ gbé wà, titi ilẹ fi mọ́.

27 Oluwa rẹ̀ si dide li owurọ̀, o si ṣi ilẹkun ile na, o si jade lati ba ọ̀na rẹ̀ lọ: si kiyesi i obinrin na, àle rẹ̀, ṣubu lulẹ li ẹnu-ilẹkun ile na, ọwọ́ rẹ̀ si wà li ẹnu-ọ̀na na.

28 On si wi fun u pe, Dide, jẹ ki a ma lọ; ṣugbọn kò sí ẹniti o dahùn: nigbana li ọkunrin na si gbé e lé ori kẹtẹkẹtẹ, ọkunrin na si dide, o si lọ si ilu rẹ̀.

29 Nigbati o dé ile rẹ̀, on si mú ọbẹ, o si mú àle rẹ̀ na, o si kun u ni-ike-ni-ike, o si pín i si ọ̀na mejila, o si rán a lọ si gbogbo àgbegbe Israeli.