27 Oluwa rẹ̀ si dide li owurọ̀, o si ṣi ilẹkun ile na, o si jade lati ba ọ̀na rẹ̀ lọ: si kiyesi i obinrin na, àle rẹ̀, ṣubu lulẹ li ẹnu-ilẹkun ile na, ọwọ́ rẹ̀ si wà li ẹnu-ọ̀na na.
28 On si wi fun u pe, Dide, jẹ ki a ma lọ; ṣugbọn kò sí ẹniti o dahùn: nigbana li ọkunrin na si gbé e lé ori kẹtẹkẹtẹ, ọkunrin na si dide, o si lọ si ilu rẹ̀.
29 Nigbati o dé ile rẹ̀, on si mú ọbẹ, o si mú àle rẹ̀ na, o si kun u ni-ike-ni-ike, o si pín i si ọ̀na mejila, o si rán a lọ si gbogbo àgbegbe Israeli.
30 O si ṣe, ti gbogbo awọn ẹniti o ri i wipe, A kò ti ìhu irú ìwa bayi, bẹ̃li a kò ti iri i lati ọjọ́ ti awọn ọmọ Israeli ti gòke ti ilẹ Egipti wá titi o fi di oni-oloni: ẹ rò o, ẹ gbimọ̀, ki ẹ si sọ̀rọ.