25 Benjamini si jade si wọn lati Gibea wa ni ijọ́ keji, nwọn si pa ninu awọn ọmọ Israeli ẹgba mẹsan ọkunrin; gbogbo awọn wọnyi li o nkọ idà.
26 Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati gbogbo awọn enia na gòke lọ, nwọn wá si Beti-eli, nwọn sọkun, nwọn si joko nibẹ̀ niwaju OLUWA, nwọn si gbàwẹ li ọjọ́ na titi di aṣalẹ; nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju OLUWA.
27 Awọn ọmọ Israeli si bère lọdọ OLUWA, (nitori ti apoti majẹmu Ọlọrun mbẹ nibẹ̀ li ọjọ́ wọnni.
28 Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni si nduro niwaju rẹ̀ li ọjọ́ wọnni,) wipe, Ki emi ki o ha si tun gbogun jade si Benjamini arakunrin mi bi? tabi ki emi ki o dẹkun? OLUWA si wipe, Ẹ gòke lọ; nitoripe li ọla emi o fi i lé ọ lọwọ.
29 Israeli si yàn awọn enia ti o ba yi Gibea ká.
30 Awọn ọmọ Israeli si gòke tọ̀ awọn ọmọ Benjamini lọ ni ijọ́ kẹta, nwọn si tẹ́gun si Gibea, gẹgẹ bi ìgba iṣaju.
31 Awọn ọmọ Benjamini si jade tọ̀ awọn enia na lọ, a si fà wọn kuro ni ilu; nwọn si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn enia, nwọn npa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju; li opópo wọnni ti o lọ si Beti-eli, ati ekeji si Gibea, ni pápa, nwọn pa ìwọn ọgbọ̀n ọkunrin ninu Israeli.