1 AWỌN ọkunrin Israeli si ti bura ni Mispe, pe, Ẹnikan ninu wa ki yio fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Benjamini li aya.
2 Awọn enia na si wá si Beti-eli, nwọn si joko nibẹ̀ titi di aṣalẹ niwaju Ọlọrun, nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun gidigidi.
3 Nwọn si wipe, OLUWA, Ọlọrun Israeli, ẽṣe ti o fi ri bayi ni Israeli, ti ẹ̀ya kan fi bùku li oni ninu awọn enia Israeli?
4 O si ṣe ni ijọ́ keji, awọn enia na dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si mọ pẹpẹ kan nibẹ̀, nwọn si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia.
5 Awọn ọmọ Israeli si wipe, Tali o wà ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli ti kò bá ijọ gòke tọ̀ OLUWA wá? Nitoripe nwọn ti bura nla niti ẹniti kò ba tọ̀ OLUWA wá ni Mispe, wipe, Pipa li a o pa a.
6 Awọn ọmọ Israeli si kãnu nitori Benjamini arakunrin wọn, nwọn si wipe, A ke ẹ̀ya kan kuro ni Israeli li oni.